OLUWA mbo; ayé o mi Yoruba Hymn

 OLUWA mbo; ayé o mi,

Oke y'o sidi n'ipo won,

At' irawo oju orun,

Y'o mu imole won kuro.


Oluwa mbo; bakan naa ko,

Bi o ti wa n'irele ri;

odo-aguntan ti a pa,

eni-iya ti o si ku.


Oluwa mbo; ni eru nla,

L'owo ina pelu ija,

L'or' iye apa Kérúbù,

Mbo, Onidajo arayé.


Eyi ha ni eni ti n rin,

Bi ero l'opopo ayé?

Ti a se 'nunibini i?

A! eni ti a pa l'eyi?


Ika: b'e wo 'nu apata,

B'e wo 'nu iho, lasan ni;

Sugbon igbagbo t'o segun

Y'o korin pe, Oluwa de.AMIN

Comments

Popular posts from this blog

Soundcheck Africa ft. Tim Godfrey and Xtreme - Living God Lyrics

Elijah Akintunde - Baba tin ba yin o mo ya Alaimore MP3 DOWNLOAD

Lizzy McAlpine – hate to be lame Lyrics