Aye Ope Yo full lyrics by Adeyinka Alaseyori

 E se Aye ope yo

E se toripe aye ope yo

E se Aye ope yo o

Emi awon woli o

Aye ope pada yo


Gbogbo ale ta sun ta ji, aye ope kan ni

Gbogbo igba ta ba sun lale,

Ta o ranti lati Gbadura, e o gba ki ile wo pa wa lat'oju orun wa saye

Aimoye igba ta ma ji, ta ma ma sare pe a ti late Otun d'abo bo wa o

O f'aye gba satani lati yo ayo isegun lori aye wa

Aye ope pada yo

L'ati ile loti mu wa o mu wa joko pelu awon omo alade

O f'aye gba wa laarin awon omo alade ilu wa

A wa n'soro nibi giga

Mo ki o toripe aye ope yo o

Emi awon woli o

Aye ope pada yo

Melo leebu awon eyan lara wa, to gbon danu Pelu eri

Melo ni awa to ti rope,

Ohun rere o le ti Inu wa jade,

To funrugbin ohun rere sinu wa to Tun jeyo

Mo ki o toripe aye ope yo o

After all we've been through

Aye ope pada yo

Igba kan ri won da'so fun o ko to di pe awon Omo to bi ri aso wo ni o

Igba kan ri won da'so fun o ko to di pe

Awon Omo to bi ninu re r'aso bo ihoho won

Igba kan ri o pelu awon ton gbe kiri

Lati ma toro Owo loju titi ese oloore toripe

Aye ope pada yo

Ah

Aye ope yo

O se aye ope yo

O se Aye ope yo o

Emi awon woli o

Aye ope pada yo


Igba ti o si nkankan se pe aye ope le yo

Igba ti gbogbo ohun gbogbo doju ru se pe aye Ope tun le yo

Ki la o ni dupe fun nigbati aye ope ti yo o

After all we've been through

Aye ope pada yo

Igba kan ri won pe o l'agan o

Sugbon lowolowo o pada gbomo jo

Igba kan ri won sa fun o lawujo awon eyan gidi

Sugbon lowolowo o ti joko pelu awon olola

Igba kan ri oo won ti write e off pe ohun rere o le Tinu re

Jade wa, won ti write e off pe ohun rere o Le tinu re jade wa

Sugbon emi Inu awon woli,

Agbanilagbatan Agbani ma gbowo,

Arugbo ojo jojo ninu eni to Fun ojo loju lati ma yo

Ninu re ni ojo tin je ojo o, ojo to yo ninu re lo Jo

Oju ton riran ninu okunkun birimu birimu

Eni nla ton se ohun nla

Eni nla ton se ohun ari tokasi

Eyan a ma gbe oyun sinu, fun gbogbo osu mesan, iwo na ni abo won

Eni aye de oyun mo ninu fun odun meji,

Meeta, meerin, maarun, meefa logan to ba o pade

O tu won sile lai gba ohunkohun rara

Emi awon woli o

O se o, toripe aye ope pada yo

Aimoye oloyun to yo ninu ewu

Aimoye trailer to subu Lu motor

O je a si lara won

A o gbe ounje pari, a le mai si nibi toye Ka wa

Sugbon a dupe ibi te ba wa de

Kinihun eya Judah aye ope pada yo

Ohun gbogbo lo se fun mi

Ohun gbogbo lo se fun mi

Ki lo ti se fun mi ko si o

Ohun gbogbo lo se fun mi

O fun mi lomo bi o se o

O fun mi loko fe o se o

Iwo to gbe mi jade lati inu ira

To fo mi laso mo

Iwo to pin okun pupa niya lai se pe

Omi ya lu Awon omo isreali lojo yen

Bawo lo se se, iwo ni o kabiyesi olola, iwo na ni

Ohun gbogbo lo se fun mi

Ohun gbogbo lo se fun mi

Ki lo ti se fun mi ko si o

Ohun gbogbo lo se fun mi

Gbogbo ojo lon d'abo bo mi lon yo mi ninu ewu

Lara ohun to se fun mi ti mi o le so

Ni emi ti mon Mi sinu to o gba lowo mi

Lara ohun to se fun mi ti mi o le so tan ni oju Iriran,

Ese ton rin, owo ton sise,

Eti ton gboran, Speaker to soro jade ninu mi o be o

Ohun gbogbo ma lo se ninu ohun gbogbo

Aimoye ijakadi lile to ja lori oro mi loru moju

Iwo lo se, iwo lo je ohun gbogbo ninu ohun Gbogbo,

Atobi tan o, atoba tan, a to Baba ma pe Enikeni ni Baba

Iwo ni o o o

Oro tin gbe'nu Omo eniyan f'ohun

Oro ton gbe inu ikoko tu asiri won ni gbangba

Oju to ri okunkun ninu okunkun o

Oju to la okunkun loju ninu okunkun birimu Birimu, iwo na ni

Baba mi o o o

A dun f'oro lo, a to ba soro, a to f'ise ogun ran,

A to Baba ma pe Enikeni ni Baba,

Aridunnu mi nigba Ti ibanuje de,

Owo ton gba ibi kuro loju ona Wa, iwo ma ni, iwo ma ni o

Iwo ni, iwo ma ni o

Iwo ni Baba mi o, iwo ni ore mi

Bawo lo se se

Ti igi fi koja lo sinu omi to magnet irin wa sori Omi,

Aake to jabo sinu omi lojo yen igi lo

Fi gbe jade, owo airi re lon sise agbara o

Owo airi re lo se wonder lojo yen

Iwo ni, iwo ma ni

Bawo lo se se

Obinrin onisun eje laarin egbegberun

Eniyan ton Lon, ase jade Lara re Logan lo mo o

O koja lo sorisun isun eje odun mejila, loba gbe Lesekese o,

Awon oni dokita ati babalawo won ti Gba, gbogbo eyan ti gba,

Woli ika ti gba, real woli Ti gba,

Sugbon Logan ti o ba o pade lo rowo Agabara

Bawo lo se se

Iwo ni, iwo lo ye

Odi Jericho, o subu pelu ariwo leekan sooso

Bawo lo se se

Awon omo isreali rin l'aginju fun odidi

Ogoji Odun, bata won o je, aso won o gbo

Iwo ni asiri ton so won di tuntun lojojumo

Bawo lo se se o kabiyesi olola

Bawo lo se se oni wonder ton gbe wonder mi o

Iyanu ton ya aye lenu, bawo lo se se

Oni wonder oni wonder o se o

Emimimo bawo lo se se

Ti iyo kekere fi trace arin omi,

Ko disappear to fi De orisun isale odo mara,

O so di didun, o so di Didun, o so odo mara di didun

Oni wonder oni wonder o se

Jesu oni wonder o se o

Jesu oni wonder o se o

Jesu oni wonder o seun

Eru ton d'eru b'eru o

Eru t'eru ri to sa t'eru o le ba o

Erujeje ton d'eru b'eru o

Eru re ba mi olodu to mo gbogbo are patapata

Ina loju, ina lenu

Gbogbo ara kikida ase

Ibi to ba de l'ase duro si

Ibi to ba si iyanu o ki le sele o

Ninu re ni aragba yamuyamu iyanu ngbe ti o

Le Tan, orisun iyanu, orisun ara, inu re ni

Oni wonder oni wonder o se

Jesu oni wonder o se o

Jesu oni wonder o se o

Jesu oni wonder o se o

Iwo l'ariwo to ta laarin awon egungun gbigbe

Iwo lo so egungun gbigbe di aye ti ori wa orun

Ri Ti orun wa ara won ri ti won o miss ara won

Iwo l'asiri ton gba yitiyiti ninu osumare

Asiri ta wa ta o ri, iwo na ni

E ru, oba eru, oba eru

Eru re to ba o

E ru, oba eru, oba eru

Eru re to ba o

Eru ton d'eru b'eru

Eru t'eru o le ba o

Erujeje t'eru o le ba o

Eru re to ba o

E ru, oba eru, oba eru

Eru re to ba o

Eni ti gbogbo aye binu si, wa ma yonu si

Eru ni o

Eni ti gbogbo aye pada leyin re, wa ma fa mora

Eru ni o

Eni ti gbogbo aye nda lebi, wa ma da won lare

Eru ni o

E ru

Eru re to mi ba o

E ru, oba eru, oba eru

Eru re to ba o

E ru, oba eru, oba eru

Eru re to ba o

Gbogbo eda to ti write off, wa ma si new Chapter fun won

Eru re to mi ba o

E ru, oba eru

Eru re to mi ba o

Please Kindly drop a comment, Corrections and suggestions. Your Comment is a motivating factor for wikilyrics to perform greatly.

Post a Comment

0 Comments
* Please Don't Spam Here. All the Comments are Reviewed by Admin.

Ads Area