Browse Lyrics A-Z
A | B | C | D | E | F | G | H | I | J | K | L | M | N | O | P | Q | R | S | T | U | V | W | X | Y | Z

CACGHB Yoruba Hymn 2 Ife Orun Alailegbe

1. Ife orun alali'egbe,
   Ayo orun sokale,
   Fi okan wa se 'bugbe Re,
   Se asetan anu Re.

2. Jesu Iwo ni alanu
   Iwo l'onibu ife
   Fi igbala Re be wa wo
   M'okan eru wa duro

3. Wa, Olodumare, gba wa
   Fun wa l'ore-ofe Re.
   L'ojiji ni k'o pada wa,
   Ma si fi wa sile mo;

4. Iwo l'a o ma yin titi,
   Bi won ti'nse ni orun
   Iyin wa ki yoo lopin
   A o s'ogo n'nu 'fe Re.

5. S'asepe awa eda Re
   Je k'awa lailabawon
   K'a ri titobi 'gbala Re
   Li aritan ninu Re.

6. Mu wa lat'ogo de ogo,
   Titi di ibugbe wa;
   T' ao fi ade wa juba Re
   N'iyanu, ife, iyin.
AMIN

download mp3


Do you Love Wikilyrics? Drop Comments & and follow us on Instagram
Related Lyrics

Post a Comment

0 Comments


Disclaimer: All The mp3 Lyrics, Hymn, Poem & Anthem on Wikilyrics are submitted by various people and they have right on the contents they submitted, all the Contents on our database is for educational purposes only and are made available for free download.