CACGHB Yoruba Hymn 4: Oluwa mi, mo njade lo

1. Oluwa mi, mo njade lo,
   Lati se ise onjo mi;
   Iwo nikan l'emi o mo
   Loro, lero, ati n'ise

2. Ise t'o yan mi l'anu Re,
   Jeki nle se tayo tayo,
   Ki nr'oju Re n'nu ise mi,
   K'emi si le fi 'fe Re han

3. Dabobo mi lowo danwo,
   K'opa okan mi mo kuro
   Lowo aniyan aye yi
   Ati gbogbo ifekufe.

4. Iwo t'oju Re r'okan mi,
   Ma wa l'ow'otun mi titi,
   Ki nma sise lo l'ase Re,
   Ki nf'ise mi gbogbo fun O.

5. Je ki nreru Re t'o fuye,
   Ki nma sora nigba gbogbo
   Ki nma f'oju si nkan t'orun
   Ki nsi mura d'ojo'ogo.

6. Ohunkohun t'O fi fun mi,
   Je ki nle lo fun ogo Re,
   Ki n f'ayo sure ije mi,
   Ki nba O rin titi d'orun
AMIN 
Please Kindly drop a comment, Corrections and suggestions. Your Comment is a motivating factor for wikilyrics to perform greatly.

Post a Comment

0 Comments
* Please Don't Spam Here. All the Comments are Reviewed by Admin.

Ads Area

Disclaimer: All The Lyrics, Stories, Hymn, Poem & Anthem on Wikilyrics are submitted by various people and they have right on the contents they submitted, all the Contents on our database is for educational purposes only and are made available for free download. If you feel one of your asset should not be here please request take down.