1. Krist' f'ogo Re ka aye,
Krist, Imole Otito;
Orun ododo dide,
K'o si bori okunkun
'mole ooro, sunmo mi,
'Rawo oro yo n'nu mi
2. Ooro to de laisi Re,
Ookun on 'banuje ni,
Ile to mo ko l'ayo,
Bi nko r'oye anu Re,
B'Iwo ko fi 'mole Re
Kan oju on okan mi
3. Nje be okan mi yi wo,
Le okunkun ese lo,
F'imole orun kun mi,
Si tu aigbagbo mi ka
Maa f'ara Re han mi si
Titi di ojo pipe
AMIN
Do you Love Wikilyrics? Drop Comments & and follow us on Instagram
0 Comments