1. Ninu gbogbo ewu oru,
Oluwa l'o so mi;
Awa si tun ri 'mole yi
A tun te ekun ba.
2. Oluwa, pa wa mo l'oni,
Fi apa Re so wa;
Kiki awon ti'wo pamo,
L'o nyo ninu ewu.
3. K'oro wa, ati iwa wa,
Wipe, tire l'awa;
Tobe t'imole otito
Le tan l'oju aye.
4. Ma je k'a pada lodo Re,
Olugbala owon;
Titi ao f'oju wa ri
Oju Re li opin.
AMIN
Please Kindly drop a comment, Corrections and suggestions. Your Comment is a motivating factor for wikilyrics to perform greatly.