CACGHB Yoruba Hymn 17 Oluwa, emi yio korin
1. Oluwa, emi y’o korin
Anu at’idajo;
Nigbawo n’Iwo y’o fun mi
N’imole on iye
2. Mo nfe lati t’ona pipe,
Ki nni okan pipe,
Ona, okan ati ile,
Nibiti Iwo mbe
3. Mo nfe ki awon oloto
Je oluranwo mi;
Ki nfi won s’ore-imule
A t’omo-odo mi.
4. Ki yo si eke at-etan
Ninu ibugbe mi;
Oluwa, Jek’Ibugbe mi
Ye fun O lati gbe!
AMIN