CACGHB Yoruba Hymn 20 Orun fere wo na
1. Orun fere wo na,
Ojo lo tan
K’ife k’o ji dide
Korubo asale
2. Bi Jesu l’origi,
Ti teriba,
T’O jowo emi Re
Le Baba Re lowo
3. Be ni mo f’emi mi
Fun l’a fun tan,
Ni ‘pamo re mimo
L’emi gbogbo sa wa
4 . Nje emi o simi
Lodo Re je,
Laije k’ero kan so
Yo okan mi lenu
5. ‘Fe Tire ni sise
L’onakona;
Mo d’oku s’ara ni
Ati s’ohun gbogbo
6. Be l’emi ye; sugbon
Emi ko, On
Ni mbe laye n’nu mi,
L’agbara ife Re.
7. Metalokan mimo,
Olorun kan
Lae ki nsa je Tire
K’ On je t’emi titi
AMIN