Wa ba mi gbe, ale fere le tan;
Okunkun nsu, Oluwa ba mi gbe
Bi Oluranlowo, miran ba ye,
Iranwo alaini, Wa ba mi gbe.
2. Ojo aye mi nsare lo s'opin
Ayo aye nku, ogo re nwomi,
Ayida at'ibaje ni mo n ri,
'Wo ti ki yipada, wa ba mi gbe.
3. Ma wa l'eru b'Oba awon oba
B'oninure, wa pelu 'wosan Re,
Ki O si ma kanu fun egbe mi,
Wa, Ore elese, wa ba mi gbe.
4. Mo nfe O ri, ni wakati gbogbo
Kilo le segun esu b'ore Re?
Tal'o le se amona mi bi Re?
N'nu 'banuje at'ayo ba mi gbe.
5. Pelu 'bukun Re, eru ko ba mi
Ibi ko wuwo, ekun ko koro,
Oro iku da? Segun isa da?
Un o segun sibe, b'Iwo ba mi gbe
6. Wa ba mi gbe, ni wakati iku,
Se 'mole mi si toka si orun
B'aye ti nkoja, k'ile orun mo,
Ni yiye, ni kiju, wa ba mi gbe.
AMIN