1. Baba, a tun pade l'oko Jesu,
A si wa teriba lab'ese Re,
A tun fe gb'ohun wa s'oke si O
Lati wa anu, lati korin 'yin
2. A yin O fun itoju 'gba gbogbo
Ojojumo l'a o ma rohin 'se Re,
Wiwa laye wa, anu Re ha ko
Apa Re ki O fi ngba 'ni mora.
3. O se! A ko ye fun ife nla Re,
A sako kuro lodo Re poju,
Sugbon kikan kikan ni o si npe
Nje a de a pada wa 'le Baba
4. Nipa ooko t'o b'or' ohun gbogbo
Nipa ife t'o ta 'fe gbogbo yo
Nipa eje ti a ta fun ese,
Silekun anu, si gba 'ni s'ile
AMIN
Please Kindly drop a comment, Corrections and suggestions. Your Comment is a motivating factor for wikilyrics to perform greatly.