1. Lekan si, bi orun ti nran,
Awa mbe Olorun
Pe ki 'mole Re ailopin
S'amona wa loni
2. K'a mase da esekese,
K'a ma si ro ibi;
K'a ni otito gan l'enu
Ati ife l'okan
3. L'ojo oni, Olugbala,
K'a ri iranwo Re,
Lati gba wa lowo esu,
Ti nd'ode wa kiri
4. Ki ise wa l'ojojumo
Ma je fun iyin Re,
Be l'o ma mbukun ise wa
Ta mbere ninu Re.
5. Je ka fi iwontunwonsi
Kawo 'fekufe wa,
Ki 'gberaga asan ara,
Ma bori okan wa
6. Olorun Baba at'Omo
Ati Emi Mimo
Ni ki Eda at'Angeli
F'ogo ailopin fun.
AMIN
Please Kindly drop a comment, Corrections and suggestions. Your Comment is a motivating factor for wikilyrics to perform greatly.