CACGHB Yoruba Hymn 18 Ogo fOlorun lale yi
1. Ogo f’Olorun l’ale yi
Fun gbogbo ore Imole,
So mi, Oba awon Oba
L’abe ojiji iye Re.
2. Oluwa f’ese mi ji mi,
Nitori omo Re, loni
K’emi le wa l’a alafia,
Pelu iwo ati aye
3. Je k’okan mi le sun le O,
K’orun didun p’oju mi de,
Orun ti y’o m’ara mi le,
Ki nle sin O li owuro
4. Bi mo ba dubule laisun,
F’ero orun kun okan mi,
Ma je ki nl’ala bururu,
Ma je k’ipa okun bo mi
5. Yin Olorun, Ibu ore;
E yin, eyin eda aye,
E yin, eyin eda Orun,
Yin Baba, Omo on Emi
AMIN