1. L'ojojumo l'a ngbe O ga
Nigbati ile ba mo,
T'a ba kunle lati yin O
Fun anu ti owuro
2. L'ojojumo l'angbe O ga
Pel' orin n'ile-eko,
L'ojojumo, pelu iyin,
L'a nse ise wa gbogbo.
3. L'ojojumo l'a ngbe O ga
Ninu orin k'a to sun
Awon angel' gbo, won si nso
Awon aguntan Kristi
4. L'ojojumo l'a ngbe O ga
Ki se ni iyin lasan;
Otito ati igboran
Nf'ogo Re han ninu wa.
5. L'ojojumo l'a ngbe O ga
Gba t'a ngbiyanju fun krist'
Lati ma farada iya
K'a pa ese run n'nu wa.
6. L'ojojumo l'a ngbe O ga
Tit' ojo wa y'o fi pin
Tao simi n'nu lala gbogbo
L'alafia d'ojo Re
AMIN
Please Kindly drop a comment, Corrections and suggestions. Your Comment is a motivating factor for wikilyrics to perform greatly.